MO SA DI O (Lyrics) by Evang (Dr) Yemi Owolabi RootofJesse
- rootofjesse96
- Sep 1, 2022
- 2 min read

Mo sa di O
Olorun Ayeraye
Mo sa di O,
Apata Israeli
Mo sa di O
Eli Eli LAMA SABACHTANI
Mo sa di O o.
Olorun awon Olorun.
1. Okunkun su birimu, birimu, Eda ko lee ran eda lowo.
Awon kan nse botiwu won, awon kan ndogbon si.
Mo rantii boo ti pemi, ati ikilo tio fun mi
Lo je n pinu lati ro mo O toba dun boba tun kan
Mo sa di O
Olorun Ayeraye
Mo sa di O,
Apata Israeli
Mo sa di O
Eli Eli LAMA SABACHTANI
Mo sa di O o
Olorun awon Olorun
2. Aginju laye , mi o le daarin
Ogbon orii mi kere
Mumi dani lowo Re
Kin ma rin jinna sako lo
L'aginju aye kinma jin sofin
Koju ti esu lori mi
Gbemi wo, so mi d'alagbara
Mumi jogun pepe agbara Re
Mo sa di O
Olorun Ayeraye
Mo sa di O,
Apata Israeli
Mo sa di O
Eli Eli LAMA SABACHTANI
Mo sa di O o
Olorun awon Olorun
3. Aso ala ni mo wo
Ma gba kaye ta epo si
Asise o ye mi, Olugbala
Gba mi lowo bilisi
Kin ma di irira loju Re
Ati ibi ti mo fin wu O
Kin ma didakuda mo O lowo, Jesu
Iwo sa ni O maa to mi
_________
Bi mo wole, ki n ri ire
Amin
Bi mo jade, kire o wa bami
Amin
Eni oke lo pe mi, kin ma rele
Oro Re ko se mo mi lara
Alaigbagbo ko ti pase mi, ri didara Olorun
Eri mi ko polongo Jesu, de opin ile aye
Mo sa di O
Olorun Ayeraye
Mo sa di O,
Apata Israeli
Mo sa di O
Eli Eli LAMA SABACHTANI
Mo sa di O o
Olorun awon Olorun
4. Gbami ko segun ika,
to lo kubi ti un o gbe gba
Won fe ki n gbaye sugbon
won o fe ki n rogo lo
Kileredi iwaye mi
Bogo o tan, ko debi to ye ko de
Olorun ni O, o kii seniyan, fina sedajo won
_________
Eni gbiyanju ibi lori mi o
Bere gbe e, eru re ni
Eni fibi ranse ninu afefe si mi
Bere gbe e, eru re ni
Iwo ton bami sore, totun dodee mi
Bere gbe e, eru re ni
Eni w'ogbo igbale nitori mi
Bere gbe e, eru re ni
Eni tafa idaloro sinu ile mi
Bere gbe e, eru re ni
Eni fe faisan demi mole
Bere gbe e, eru re ni
Oya oya bere gberu ibi re
Bere gbe e, eru re ni
Awon ta jo n sare ije pelu inu kan
A o jo debi ogo ni
The lyrics are so amazing, the inspiration of the Almighty. God bless you as you release sound from his throne. Lydia Oluwatosin